1. Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ àrólé nítorí pé, ó jẹ́ ẹ̀dá tí yóò máa bímọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ náà yóò máa bímọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn mọlāika kò sì lè jẹ́ àrólé nítorí pé, bíbí ọmọ kò sí nínú ìṣẹ̀dá tiwọn.
1. Ìforíkanlẹ̀-kíni èyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘āla - pa láṣẹ fún àwọn mọlāika Rẹ̀, ó ti di èèwọ̀ fún ìjọ Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Èyí ni pé, kò bá òfin ’Islām mu fún ẹnikẹ́ni láti forí kanlẹ̀ kí ẹlòmíìràn, ẹni yòówù ìbáà jẹ́. 2. ’Iblīs ni àlàjẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣaetọ̄n. Àwọn kan kà á mọ́ ara àwọn mọlāika. Wọ́n tún lérò pé Ṣaetọ̄n jẹ́ onímọ̀-jùlọ àti olùjọ́sìn-jùlọ láààrin àwọn mọlāika ṣíwájú kí ó tó di ẹni-ẹ̀kọ̀. Àmọ́ sá, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹyọ kan nínú àwọn àlùjànnú ni ’Iblīs, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Kahf; 18:50. Allāhu kò sì fi ìmọ̀ àti ìjọ́sìn ròyìn Ṣaetọ̄n rí.
1. Nípa èso tí Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - jẹ, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Arọ̄f; 7:22.