1. Ìforíkanlẹ̀-kíni èyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘āla - pa láṣẹ fún àwọn mọlāika Rẹ̀, ó ti di èèwọ̀ fún ìjọ Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Èyí ni pé, kò bá òfin ’Islām mu fún ẹnikẹ́ni láti forí kanlẹ̀ kí ẹlòmíìràn, ẹni yòówù ìbáà jẹ́. 2. ’Iblīs ni àlàjẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣaetọ̄n. Àwọn kan kà á mọ́ ara àwọn mọlāika. Wọ́n tún lérò pé Ṣaetọ̄n jẹ́ onímọ̀-jùlọ àti olùjọ́sìn-jùlọ láààrin àwọn mọlāika ṣíwájú kí ó tó di ẹni-ẹ̀kọ̀. Àmọ́ sá, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹyọ kan nínú àwọn àlùjànnú ni ’Iblīs, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Kahf; 18:50. Allāhu kò sì fi ìmọ̀ àti ìjọ́sìn ròyìn Ṣaetọ̄n rí.