1. Kíyè sí i, ìtúmọ̀ àkànlò ni wọ́n lò fún “aró” nínú āyah yìí. “Aró” sì dúró fún ẹ̀sìn. Kókó ìtúmọ̀ rẹ̀ sì ni pé, ẹ̀sìn gbọ́dọ̀ hàn lára olùjọ́sìn fún Allāhu gẹ́gẹ́ bí aró ṣe máa ń hàn lára aṣọ tí wọ́n bá pa láró.
1. Kókó tí āyah yìí ń fi rinlẹ̀ ni pé, kò sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ Allāhu kan tó ṣe ẹ̀sìn yẹ̀húdí tàbí nasọ̄rọ̄ tàbí ìbọ̀rìṣà. ’Islām ni ẹ̀sìn tí gbogbo wọn ṣe - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá wọn -.