1. Èyí ni pé, kí ìdájọ́ tí ó wà nínú āyah kan di ohun tí a ò níí lò mọ́ nítorí ìdájọ́ titun tí āyah mìíràn mú wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn āyah ìdájọ́ kan tí ó sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn Hijrah (āyah Mọdaniyyah) ṣe pa ìdájọ́ àwọn āyah tí ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú Hijrah (āyah Mọkiyyah) rẹ́ àti gẹ́gẹ́ bí àwọn āyah ìdájọ́ kan tí ó sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ọdún ìparí nínú ìlú Mọdīnah ṣe pa àwọn āyah ìdájọ́ kan tí ó sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ nínú ìlú Mọdīnah rẹ́.
1. Ìyẹn ni pé, ẹni tí ó bá ṣe ’Islām pẹ̀lú àfọ̀mọ́-ọkàn. 2. Ìyẹn ni pé, kò níí sí ìbẹ̀rù fún àwọn mùsùlùmí nípa ohun tí wọ́n ń lọ bá pàdé ní Ọjọ́ Àjíǹde. 3. Ìyẹn ni pé, kò níí sí ìbànújẹ́ fún àwọn mùsùlùmí nípa ohun tí ọwọ́ wọn kò bà nínú oore ayé nítorí pé, Allāhu máa dí i fún wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde.