1. Fífi ìnira gba ààwẹ̀ lè jẹ́ nípasẹ̀ ogbó, àmódi ọlọ́jọ́ gbọọrọ, oyún tàbí fífún ọmọ lọ́yàn.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106. 2. “ọ̀rọ̀-ìpínyà”: ni ọ̀rọ̀ tó ń ṣe ìpínyà láààrin òdodo àti irọ́. 3. Kíyè sí i, awẹ́ gbólóhùn yìí “famọn ṣẹhida minkum-ṣṣahr fal yẹsumhu” kò túmọ̀ sí “nítorí náà, ẹni tí ó bá rí oṣù, kí ó gba ààwẹ̀” nítorí pé, nínú gírámà èdè Lárúbáwá, kalmọh “aṣ-ṣahrọ” nínú awẹ́ gbólóhùn náà kì í ṣe “mọf‘ūlun bih” (àbọ̀) fún “ṣẹhida” bí kò ṣe “ṭḥọrfu-zzamọ̄n” (ọ̀rọ̀-àpọ́nlé / àrótì fún àsìkò). Bákan náà, kì í ṣe gbogbo ènìyàn l’ó máa ní àǹfààní láti rí ìlétéṣù ní alẹ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù Rọmọdọ̄n. Àti pé Ohun tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ nípa ìbẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n àti ìparí rẹ̀ ni pé “Ẹ gba ààwẹ̀ fún rírí ìlétéṣù. Ẹ túnu fún rírí ìlétéṣù. Tí wọ́n bá fi ẹ̀sújò bò ó lójú fún yín, ẹ parí òǹkà (ọgbọ̀n ọjọ́ fún oṣù Ṣa‘bān àti ọgbọ̀n ọjọ́ fún oṣù Rọmọdọ̄n) Bukọ̄riy àti Muslim. Àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “fún rírí ìlétéṣù” ń túmọ̀ sí “tí wọ́n bá rí ìlétéṣù” tàbí “tí ẹ bá rí ìlétéṣù”. Bákan náà, ó pọn dandan kí gbogbo ayé gun òkè ‘Arafah ní ọjọ́ kan náà nítorí pé, àyè kan náà ni òkè ‘Arafah wà, ṣùgbọ́n kò pọn dandan kí gbogbo ayé bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ kan náà, kò sì pọn dandan kí gbogbo ayé parí ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ kan náà. Èyí kò wá túmọ̀ sí pé kí odidi ìlú méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú orílẹ̀ èdè kan ṣoṣo bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí parí ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, ní orílẹ̀ èdè wa Nàìjíríà ní àpapọ̀, tí a bá fẹ́ kí ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n wa àti ìparí rẹ̀ máa jẹ́ ọjọ́ kan náà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe bá òfin ’Islām mu, a bùkátà sí n̄ǹkan méjì gbòòrò. Ìkíní: aṣíwájú ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa jẹ́ onisunnah, tí àṣẹ rẹ̀ sì máa múlẹ̀ dáadáa. Ìkejì: ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìlétéṣù, ètò àti ìgbédìde ikọ̀ olùwá-oṣù. Láì sí ìkíní kejì, ìtàsé ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n wa kò níí yé máa fi ọjọ́ ẹyọ kan tàbí ọjọ́ méjì tàsé ara wọn. W-Allāhu-l-musta‘ān.