1. Mọlaika Jibrīl tún ní àwọn orúkọ mìíràn nínú al-Ƙur’ān. Nínú àwọn orúkọ rẹ̀ ni “ar-Rūh” - Ẹ̀mí - (sūrah al-Mọ‘ārij; 70:4), “rūhul-ƙudus” - Ẹ̀mí Mímọ́ - (sūrah an-Nahl; 16:102) àti “rūhul-’Amīn” - Ẹ̀mí Ìfàyàbalẹ̀, Ẹ̀mí tí kì í jàǹbá iṣẹ́ tí Allāhu fi rán an. - (sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:193).