1. Àwọn kan gbà pé mọlāika ni Hārūt àti Mọ̄rūt, àwọn mìíràn sì sọ pé wọn kì í ṣe mọlāika. W-Allāhu ’a‘lam.
1. Rọ̄‘inā jẹ́ ọ̀rọ̀ méjì; “rọ̄‘i” àti “nā”. “Nā” jẹ́ ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ẹnì kíní ọ̀pọ̀ “wa”. “Rọ̄‘i” ní ìtúmọ̀ méjì nínú èdè Lárúbáwá àti èdè Isrā’īl. Bákan náà, “rọ̄‘i” lè jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ nínú èdè méjèèjì. Nígbà tí wọ́n bá lo “rọ̄‘i” ní ìlò ọ̀rọ̀-orúkọ, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “òmùgọ̀” nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá láti ara “ru‘ūnah” agọ̀. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá lo “rọ̄‘i” ní ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “kíyè sí (i), wò (ó),” nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá láti ara “ri‘ānah” kíkíyèsí tàbí mímójútó kiní kan / ẹnì kan. Ìgbàkígbà tí àwọn yẹhudi bá lo “rọ̄‘i” fún àwọn Ànábì wọn, ìlò ọ̀rọ̀-orúkọ ni wọ́n ń gbàlérò. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, tí wọ́n bá sọ fún àwọn Ànábì wọn pé “rọ̄‘inā”, ohun tí wọ́n ń gbà lérò ni pé “òmùgọ̀ wa!”. Àmọ́ nígbà tí àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - bá lò “rọ̄‘inā” fún Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá a -, ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ ni wọ́n ń gbàlérò. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àwọn Sọhābah ń sọ pé “kí Ànábì kíyè sí wa”.