1. Kíyè sí i, Kaabah ni ƙiblah (àdojúkọ) àwa mùsùlùmí lórí ìrun wa, àmọ́ níwọ̀n ìgbà tí a ò bá sí nínú haram Mọkkah, agbègbè yòówù kí àdojúkọ wá bọ́ sí láààrin orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, kì í ṣe ìyẹn ni àdojúkọ wa bí kò ṣe pé ó jẹ́ ọ̀nà tààrà sí Kaabah láti ìlú wa. Àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ ni Allāhu ń júwe àwọn iṣẹ́ rere fún dípò bí wọ́n ṣe sọ ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn nìkan di ògóńgórí iṣẹ́ rere nínú ìlànà ìjọ́sìn wọn.
1. Àwọn àmì ikú ni kí ẹ̀dá lérò pé ó ṣeé ṣe kí àìsàn kan tàbí ìrìn-àjò kan yọrí sí ikú fún òun. 2. Ìyẹn ni pé, kí onídúkìá fúnra rẹ̀ pín ogún rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn , àwọn āyah mìíràn sọ̀kalẹ̀ tí ó pa ìdájọ́ yìí rẹ́. Àwọn āyah náà ni āyah tí Allāhu fúnra Rẹ̀ fi pín ogún òkú sūrah an-Nisā’; 7-14.