1. Ẹ wo āyah 213 níwájú àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:72 - 76.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:48. 2. Ọ̀nà méjì ni “kursiyy” tó jẹyọ nínú gbólóhùn yìí “Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.” túmọ̀ sí. Ìtúmọ̀ kìíní ni pé, “kursiyy” túmọ̀ sí àga gẹ́gẹ́ bí mo ṣe túmọ̀ rẹ̀ sókè yẹn. Ìtúmọ̀ kejì ni pé, “kursiyy” túmọ̀ sí ibùgbẹ́sẹ̀lé Allāhu - tó ga jùlọ - ìyẹn ni pé, àyè tí Allāhu - tó ga jùlọ - gbé ẹsẹ̀ Rẹ̀ méjèèjì le. Àpapọ̀ ìtúmọ̀ kìíní kejì ni pé, Allāhu gúnwà sí orí “al-‘Arṣ” ìtẹ́ ọlá Rẹ̀. Ó sì gbé ẹsẹ̀ Rẹ̀ méjèèjì lé orí “al-kursiyy” àga Rẹ̀. Àgá náà sì fẹjú ju àpapọ̀ àwọn sánmọ̀ méjèèjè àti àwọn ilẹ̀ méjèèjè. 3. Ọ̀kan pàtàkì nínú āyah ìṣọ́ tó nípọn ju ẹ̀wù irin ni āyah al-Kursiyy.