1. Ìyẹn ni pé, àwọn yẹ̀húdí, ṣíwájú kí Allāhu tó gbé Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dìde, wọ́n máa ń sọ fún àwọn ọ̀sẹbọ Lárúbáwá pé, “Ẹ jẹ́ tètè gba Allāhu gbọ́ ní òdodo bí bẹ́ẹ̀ kọ nígbà tí òpin Òjíṣẹ́ náà bá dé, àwọn àti òun máa parapọ̀ le yín lórí.” Àmọ́ nígbà tí òpin Òjíṣẹ́ náà - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dé, àwọn gan-an náà gbógun tì í nítorí pé, gbogbo èrò-ọkàn wọn ni pé, nínú ìran ọmọ Isrọ̄’īl ni òpin Òjíṣẹ́ náà máa ti wá. Àmọ́ nínú ìran Lárúbáwá ni Allāhu ti gbé òpin Òjíṣẹ́ náà dìde.