1. Tí ọkùnrin bá sọ pé “Mo fi Allāhu búra, èmi kò níí súnmọ́ ìyàwó mi.” Òǹkà ọjọ́ tí kò fi níí súnmọ́ ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn ìbúra náà kò gbọdọ̀ tayọ oṣù mẹ́rin.
1. Héélà mẹ́tà lè túmọ̀ sí rírí héélà mẹ́ta tàbí rírí ìmọ́ra héélà mẹ́ta. Níkété tí ìkẹta bá ti ṣẹlẹ̀, obìnrin ti jáde opó ìkọ̀sílẹ̀. 2. Ìyẹn ni pé ipò àjùlọ wà fún ọkùnrin lórí obìnrin nínú ’Islām
1. Ìyẹn ni pé, ìyàwó máa dá sadāƙi rẹ̀ padà fún ọkọ rẹ̀ nígbà tí ó bá jẹ́ pé ìyàwó fúnra rẹ̀ l’ó ní òun kò ṣèyàwó rẹ̀ mọ́.