1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mọ̄’idah; 5:5.
1. Suddiy àti Ƙọtādah túmọ̀ “’athā” sí “ìdọ̀tí”, Mujāhid túmọ̀ rẹ̀ sí “ẹ̀jẹ̀”. (Tọbariy). 2. عَنْ أَنَسٍ أَنَّ الْيَهُودَ كَانُوا إِذَا حَاضَتِ الْمَرْأَةُ فِيهِمْ لَمْ يُؤَاكِلُوهَا وَلَمْ يُجَامِعُوهُنَّ فِى الْبُيُوتِ فَسَأَلَ أَصْحَابُ النَّبِىِّ -صلى الله عليه وسلم- النَّبِىَّ -صلى الله عليه وسلم- فَأَنْزَلَ اللَّهُ تَعَالَى ( وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْمَحِيضِ قُلْ هُوَ أَذًى فَاعْتَزِلُوا النِّسَاءَ فِى الْمَحِيضِ) إِلَى آخِرِ الآيَةِ فَقَالَ رَسُولُ اللَّهِ -صلى الله عليه وسلم- « اصْنَعُوا كُلَّ شَىْءٍ إِلاَّ النِّكَاحَ ». Láti ọ̀dọ̀ ’Anas - kí Allāhu yọ́nú sí i -, “Dájúdájú àwọn yẹ̀húdí, nígbàkígbà tí obìnrin kan nínú wọn bá ń ṣe héélà lọ́wọ́, wọn kò níí bá jẹun papọ̀, wọn kò níí súnmọ́ ọn nínú ilé. Àwọn Sọhābah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì bi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - léèrè. Allāhu - tó ga jùlọ - sì sọ āyah yìí kalẹ̀. Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé, “Ẹ ṣe gbogbo n̄ǹkan àfi ìtìbọ̀.” Muslim ló gbà á wá. Ìyẹn ni pé, “Ẹ bá oníhéélà jẹun, ẹ bá a ṣeré, ẹ dìmọ́ ọn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́dọ̀ ti kálámù bọ inú ìgò tàdáà àfi lẹ́yìn ìmọ́ra àti ìwẹ̀ ìmọ́ra.”