1. Òkúǹbete ni ẹran tí ó kú fúnra rẹ̀. Kíyè sí i, ẹ̀tọ́ ni òkúǹbete ẹran odò ní tirẹ̀ ní ìbámu sí sūrah al-Mā’idah; 5:96. 2. Ìyẹn ẹ̀jẹ̀ tí ó tú jáde lára ẹran yálà nípasẹ̀ dídúńbú, gígún tàbí títalọ́fà ní ìbámu sí sūrah al-’Ani‘ām; 6:145. Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ tí ó ṣẹ́kù sára ẹran tí wọ́n ti kun tàbí ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ẹ̀dọ̀ àti àmọ́. 3. Ìnira ebi ni pé, kí ènìyàn bọ́há sí àyè kan, tí kò ti lè rí òdíwọ̀n ohun jíjẹ tàbí ohun mímu halāl tí ó kéré jùlọ láti fi gbé ẹ̀mí ara rẹ̀ ró. Àmọ́ ní ti ìnira àìsàn, mùsùlùmí kò gbọdọ̀ lo n̄ǹkan harām láti fi tọ́jú ara rẹ̀, bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, kódà kó fẹ́ já sí ikú. Harām kì í ṣe sábàbí ìlera. Nítorí náà, ìnira ebi ni làlúrí. Ìnira àìsàn kì í ṣe làlúrí.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n mú ìṣìnà, wọ́n fi ìmọ̀nà sílẹ̀, wọ́n mú ìyà, wọ́n sì fi àforíjìn sílẹ̀.