قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى- ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل

بەت نومۇرى:close

external-link copy
45 : 6

فَقُطِعَ دَابِرُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْۚ وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Nítorí náà, A pa ìjọ tó ṣàbòsí run pátápátá. Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoso, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Fātihah;1:2.

التفاسير:

external-link copy
46 : 6

قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِنۡ أَخَذَ ٱللَّهُ سَمۡعَكُمۡ وَأَبۡصَٰرَكُمۡ وَخَتَمَ عَلَىٰ قُلُوبِكُم مَّنۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَأۡتِيكُم بِهِۗ ٱنظُرۡ كَيۡفَ نُصَرِّفُ ٱلۡأٓيَٰتِ ثُمَّ هُمۡ يَصۡدِفُونَ

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá gba ìgbọ́rọ̀ yín àti ìríran yín, tí Ó sì di ọkàn yín pa, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu ni ó máa mú un wá fún yín? Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo)! info
التفاسير:

external-link copy
47 : 6

قُلۡ أَرَءَيۡتَكُمۡ إِنۡ أَتَىٰكُمۡ عَذَابُ ٱللَّهِ بَغۡتَةً أَوۡ جَهۡرَةً هَلۡ يُهۡلَكُ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلظَّٰلِمُونَ

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín ní òjijì tàbí ní gban̄gba ojúkojú, ṣé wọ́n máa pa ẹnì kan run bí kò ṣe ìjọ alábòsí!” info
التفاسير:

external-link copy
48 : 6

وَمَا نُرۡسِلُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَۖ فَمَنۡ ءَامَنَ وَأَصۡلَحَ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ

A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ náà níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí wọ́n jẹ́) oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ rẹ̀), kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
49 : 6

وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا يَمَسُّهُمُ ٱلۡعَذَابُ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ

Àwọn tó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, ọwọ́ ìyà yóò tẹ̀ wọ́n nítorí pé wọ́n máa ń yapa àṣẹ (Allāhu). info
التفاسير:

external-link copy
50 : 6

قُل لَّآ أَقُولُ لَكُمۡ عِندِي خَزَآئِنُ ٱللَّهِ وَلَآ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ وَلَآ أَقُولُ لَكُمۡ إِنِّي مَلَكٌۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّۚ قُلۡ هَلۡ يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُۚ أَفَلَا تَتَفَكَّرُونَ

Sọ pé: “Èmi kò sọ fún yín pé àwọn ilé-ọrọ̀ Allāhu wà lọ́dọ̀ mi, èmi kò sì nímọ̀ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ fún yín pé mọlāika kan ni mí. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí.” Sọ pé: “Ǹjẹ́ afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí?[1] Ṣé ẹ ò ronú jinlẹ̀ ni?” info

1. Allāhu ni Olùríran nítorí pé, Òun nìkan ni Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba.

التفاسير:

external-link copy
51 : 6

وَأَنذِرۡ بِهِ ٱلَّذِينَ يَخَافُونَ أَن يُحۡشَرُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ لَيۡسَ لَهُم مِّن دُونِهِۦ وَلِيّٞ وَلَا شَفِيعٞ لَّعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ

Fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó ń páyà pé wọ́n máa kó àwọn jọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, kò sì níí sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀.[1] (Kìlọ̀ fún wọn) kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu). info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:48.

التفاسير:

external-link copy
52 : 6

وَلَا تَطۡرُدِ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ مَا عَلَيۡكَ مِنۡ حِسَابِهِم مِّن شَيۡءٖ وَمَا مِنۡ حِسَابِكَ عَلَيۡهِم مِّن شَيۡءٖ فَتَطۡرُدَهُمۡ فَتَكُونَ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Má ṣe lé àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.[1] info

1. Āyah yìí ń sọ nípa àwọn Sọhābah tí wọ́n jẹ́ tálíkà pọ́nńbélé, gẹ́gẹ́ bí āyah 53 tí ó tẹ̀lé āyah yìí ṣe fi hàn, wọn kì í ṣe sūfī gẹ́gẹ́ bí àwọn òpùrọ́ kan ṣe lérò.

التفاسير: