1. Méjì ni ẹran tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa. Ìkíní: ẹran tí wọ́n fi orúkọ mìíràn yàtọ̀ sí orúkọ Allāhu pa, èèwọ̀ ni. Ìkejì: ẹran tí mùsùlùmí pa, àmọ́ tí ó gbàgbé láti fi orúkọ Allāhu pa á, wọ́n ṣàmójú kúrò fún un, ẹ̀tọ́ sì ni ẹran náà. Àmọ́ ìyapa-ẹnu wà lórí jíjẹ ẹran náà bí ó bá jẹ́ pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàì fi orúkọ Allāhu pa á ni.
1. Àwọn ọ̀tọ̀kùlú ni àwọn tí ẹnu wọn tọ́rọ̀ nínú ìlú, àwọn aláṣẹwàá, àwọn àgbà ìlú.
1. Ìyẹn ni pé, Allāhu lÓ nímọ̀ jùlọ nípa pàápàá ẹni tí Ó fi iṣẹ́ rán sí àwọn ènìyàn.