قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى- ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل

بەت نومۇرى:close

external-link copy
36 : 6

۞ إِنَّمَا يَسۡتَجِيبُ ٱلَّذِينَ يَسۡمَعُونَۘ وَٱلۡمَوۡتَىٰ يَبۡعَثُهُمُ ٱللَّهُ ثُمَّ إِلَيۡهِ يُرۡجَعُونَ

Ọ̀wọ́ ẹni tó ń jẹ́pè ni àwọn tó ń gbọ́rọ̀. (Ní ti) àwọn òkú, Allāhu yó gbé wọn dìde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò dá wọn padà sí. info
التفاسير:

external-link copy
37 : 6

وَقَالُواْ لَوۡلَا نُزِّلَ عَلَيۡهِ ءَايَةٞ مِّن رَّبِّهِۦۚ قُلۡ إِنَّ ٱللَّهَ قَادِرٌ عَلَىٰٓ أَن يُنَزِّلَ ءَايَةٗ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ

Wọ́n tún wí pé: “Nítorí kí ni wọn kò ṣe sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu lágbára láti sọ àmì kan kalẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
38 : 6

وَمَا مِن دَآبَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا طَٰٓئِرٖ يَطِيرُ بِجَنَاحَيۡهِ إِلَّآ أُمَمٌ أَمۡثَالُكُمۚ مَّا فَرَّطۡنَا فِي ٱلۡكِتَٰبِ مِن شَيۡءٖۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ يُحۡشَرُونَ

Kò sí ohun abẹ̀mí kan (tó ń rìn) lórí ilẹ̀, tàbí ẹyẹ kan tó ń fò pẹ̀lú apá rẹ̀ méjèèjì bí kò ṣe àwọn ẹ̀dá kan (bí) irú yín. A kò fi kiní kan sílẹ̀ (láì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀) sínú Tírà (ìyẹn, ummul-kitāb). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni wọn yóò kó wọn jọ sí. info
التفاسير:

external-link copy
39 : 6

وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا صُمّٞ وَبُكۡمٞ فِي ٱلظُّلُمَٰتِۗ مَن يَشَإِ ٱللَّهُ يُضۡلِلۡهُ وَمَن يَشَأۡ يَجۡعَلۡهُ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ

Àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́, adití àti ayaya tó wà nínú àwọn òkùnkùn ni wọ́n. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa ṣì í lọ́nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fi sójú ọ̀nà tààrà (’Islām). info
التفاسير:

external-link copy
40 : 6

قُلۡ أَرَءَيۡتَكُمۡ إِنۡ أَتَىٰكُمۡ عَذَابُ ٱللَّهِ أَوۡ أَتَتۡكُمُ ٱلسَّاعَةُ أَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَدۡعُونَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín tàbí tí Àkókò náà bá dé ba yín, ṣe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni ẹ̀yin máa pè, tí ẹ bá jẹ́ olódodo!” info
التفاسير:

external-link copy
41 : 6

بَلۡ إِيَّاهُ تَدۡعُونَ فَيَكۡشِفُ مَا تَدۡعُونَ إِلَيۡهِ إِن شَآءَ وَتَنسَوۡنَ مَا تُشۡرِكُونَ

Rárá o, Òun (nìkan) lẹ máa pè. Ó sì máa mú (ìnira) tí ẹ̀ ń pè É sí kúrò (fún yín) tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin yó sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ sí I. info
التفاسير:

external-link copy
42 : 6

وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰٓ أُمَمٖ مِّن قَبۡلِكَ فَأَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡبَأۡسَآءِ وَٱلضَّرَّآءِ لَعَلَّهُمۡ يَتَضَرَّعُونَ

Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. A sì fi àwọn ìpọ́njú àti àwọn àìlera gbá wọn mú nítorí kí wọ́n lè rawọ́ rasẹ̀ (sí Allāhu).[1] info

1. Ìrawọ́-rasẹ̀ sí Allāhu ni pé, yíyẹpẹrẹ ara ẹni fún Un, pípáyà Rẹ̀ àti ríronú-pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

التفاسير:

external-link copy
43 : 6

فَلَوۡلَآ إِذۡ جَآءَهُم بَأۡسُنَا تَضَرَّعُواْ وَلَٰكِن قَسَتۡ قُلُوبُهُمۡ وَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Wọn kò ṣe rawọ́ rasẹ̀ (sí Wa) nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn! Ṣùgbọ́n ọkàn wọn le koko. Aṣ-Ṣaetọ̄n sì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
44 : 6

فَلَمَّا نَسُواْ مَا ذُكِّرُواْ بِهِۦ فَتَحۡنَا عَلَيۡهِمۡ أَبۡوَٰبَ كُلِّ شَيۡءٍ حَتَّىٰٓ إِذَا فَرِحُواْ بِمَآ أُوتُوٓاْ أَخَذۡنَٰهُم بَغۡتَةٗ فَإِذَا هُم مُّبۡلِسُونَ

Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbàgbé ohun tí A fi ṣe ìrántí fún wọn, A ṣí àwọn ọ̀nà gbogbo n̄ǹkan sílẹ̀ fún wọn, títí di ìgbà tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ sí ohun tí A fún wọn (nínú oore ayé.), A sì mú wọn lójijì. Wọ́n sì di olùsọ̀rètínù. info
التفاسير: