1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:47.
1. Gbólóhùn yìí “Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n” ń túmọ̀ sí pé, àwọn tó nímọ̀ nípa Taorāt àti ’Injīl mọ̀ pé nínú tírà méjèèjì, ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun Ẹlẹ́dàá àti pé Òjíṣẹ́ tí wọ́n ń retí ni Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, àmọ́ wọ́n daṣọ bo òtítọ́ mọ́lẹ̀. Ìdí nìyí tí āyah 21 fi pè wọ́n ní alábòsí.
1. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ tí ó máa di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ọ̀run ni ìṣìpẹ̀ tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà wọn.