1. Ìyẹn ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyẹn ti da ọ̀rọ̀ rú mọ́ra wọn lọ́wọ́ lórí ṣíṣà tí Allāhu ṣa Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́ṣà láààrin wọn, ẹni tí àwọn náà jẹ́rìí sí jíjẹ́ olódodo àti olùfọkàntán rẹ̀ ṣíwájú kí ó tó di Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, tí wọ́n sì ń sọ ìsọkúsọ sí i lóríṣiríṣi lọ́nà àìtọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe máa dojú ọ̀rọ̀ rú mọ́ra wọn lọ́wọ́ tí ó bá jẹ́ pé mọlāika kan ni Allāhu ní kí ó jẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ láààrin wọn.
1. Irú àánú wo? Èsì rẹ̀ wá níwájú nínú āyah 54, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àànú kan tún ni lílọ́ ẹ̀dá lára títí di Ọjọ́ Àjíǹde gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, bí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kò ṣe fi apá kan mọ̀nà, kò túmọ̀ sí pé Allāhu kì í ṣe Aláàánú, kò sì túmọ̀ sí pé àánú Rẹ̀ kò lè kárí gbogbo wa ní ayé àti ní ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé bí Allāhu ṣe fi ọ̀nà tààrà Rẹ̀ ’Islām mọ apá kan kò túmọ̀ sí pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - jẹ́ alábòsí. Àmọ́ ẹ̀kọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fẹ́ kọ́ wa nínú ìwọ̀nyẹn pọ̀ púpọ̀. Nínú rẹ̀ ni pé, gbogbo ìròyìn ara Rẹ̀ l’ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ. Lára ìròyìn Rẹ̀ ni ìfinimọ̀nà àti ìṣinilọ́nà, àánú àti ìyà. Kò sí èyí tó máa ṣe àlékún ọlá Rẹ̀ nínú wọn, kò sì sí èyí tí ó máa tàbùkù ipò Rẹ̀ nínú wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni kó wòye sí ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ pẹ̀lú ọpọlọ tó mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì nítorí pé, kò sí ẹni tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - kò ní àwíjàre lórí rẹ̀.
1. Ìyẹn nínú ìjọ rẹ̀ torí pé gbogbo ànábì ló bá Islām nílé ayé.
1. Āyah yìí àti āyah 61 nínú sūrah yìí ti fi rinlẹ̀ pé, òkè lókè àwọn sánmọ̀ ni pàápàá bíbẹ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - wà pẹ̀lú títóbi Rẹ̀.