1. Láti ọ̀dọ̀ ọmọ ‘Umọr, láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó sọ pé: “A ṣe òkúǹbete méjì àti ẹ̀jẹ̀ méjì ní ẹ̀tọ́ fún wa; òkúǹbete méjì náà ni ẹja àti tata. Ẹ̀jẹ̀ méjì náà - mo rò ó sí pé Ànábì sọ pé - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ẹ̀dọ̀ àti àwọ́n.” (Sunanul-Baehaƙiy al-Kubrọ̄; 18776) 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:173. 3. Āyah yìí kò kó gbogbo ohun jíjẹ àti ohun mímu tó jẹ́ harām sínú tán nítorí pé, Allāhu - tó ga jùlọ - kàn fi fọ èsì sí ọ̀rọ̀ ẹnu àti èrò-ọkàn àwọn ọ̀ṣẹbọ ni, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ ṣíwájú nínú āyah 138-139.