1. Ìyẹn ní ti ẹni tí ó kú sínú ẹ̀sìn mìíràn lẹ́yìn Islām.
1. Kíyè sí i, gbígbé ìdájọ́ ìjìyà kan dìde lórí ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ wáyé àfi láti ọwọ́ ìjọ́ba ìlú tàbí pẹ̀lú ìyọ̀nda láti ọ̀dọ̀ ìjọba.
1. Àwọn yẹhudi rán ara wọn lọ bá Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti bi í léèrè nípa ìdájọ́ onísìná tí ó ti ṣe ìgbéyàwó rí. Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ wọn pé tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá pe ìdájọ́ rẹ̀ ní kòbókò àti kíkun ojú onísìná ní dúdú láti fi ṣẹ̀sín níta, kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìdájọ́ yẹn. Àmọ́ tí ó bá pe ìdájọ́ rẹ̀ ní lílẹ̀lókòpa, ẹ ṣọ́ra fún un, kí ẹ má ṣe tẹ̀lé e.