1. Ìyẹn ni pé, bí ẹ̀yin onítírà bá ń bú àwa onígbàgbọ́ òdodo, tí ẹ bá ń kórira wa nítorí ìgbàgbọ́ òdodo wa nínú Allāhu àti àwọn Tírà Rẹ̀, èébú wa àti ìkórira wa kò burú tó ẹ̀san tí Allāhu san yín láyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ẹ fi di ẹni ìsẹ́bilé, ẹni ìbínú, ọbọ, ẹlẹ́dẹ̀ àti ẹni tí ń bọ àwọn Ànábì kan tí wọn kò pe ara wọn ní ọlọ́hun, tí wọn kò sì yọ̀nù sí bí ẹ ṣe sọ wọ́n di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Ọ̀rọ̀ ayé yín àti ọ̀rọ̀ ọ̀run yín sì ti dàrú pátápátá.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:72.