1. Allāhu Alágbára dí àwọn ọmọ Isrọ̄’īl lọ́wọ́ lórí pípa tí wọ́n fẹ́ pa Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Allāhu kò jẹ́ kí wọ́n rí i kàn mọ́ igi àgbélébùú, kò sì jẹ́ kí wọ́n rí i pa. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:157.
1. “Hawāriyyūn” túmọ̀ sí àwọn ọmọlẹ́yìn. Ipò tí àwọn Sọhābah àti Ansọ̄r wà sí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni ipò tí àwọn hawāriyyūn wà sí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ ara wọn.