1. Al-Ƙur’ān pín ìjọ nasọ̄rọ̄ sí méjì; ìkíní ni igun tí àwọn ìròyìn tó wà nínú āyah 82 sí 84 nínú sūrah yìí wà lára rẹ̀. Igun yìí ló máa ń padà gba ’Islām ṣíwájú ọjọ́ ikú wọn. Igun yìí nìkan ló sì máa bá àwa mùsùlùmí wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah 85 nínú sūrah yìí. Igun kejì ni àwọn nasọ̄rọ̄ tí kò ní àwọn ìròyìn wọ̀nyẹn lára. Igun yìí ló máa ń takú sínú ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ti dé etí ìgbọ́ wọn. Igun yìí ló sì máa wà pẹ̀lú àwọn yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ nínú Iná gbére.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:219. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 3.