1. Ìyẹn ni pé, bí Allāhu bá fẹ́ fi ìyapa-àṣẹ tí wọ́n ṣe gbá wọn mú, má ṣe jẹ wá ní ìyà pẹ̀lú wọn. Àwọn ni wọ́n yapa àsẹ Rẹ, kì í ṣe àwa.
1. Ànábì Mūsā àti arákùnrin rẹ̀ Hārūn - kí ọlà Allāhu máa bá àwọn méjèèjì - kú sórí ìrìn-àjò ológójì ọdún náà. Ànábì Yūṣa‘ - kí ọlà Allāhu máa bá a - ló padà darí wọn wọnú ìlú náà.
1. “sao’ah” túmọ̀ sí ìhòhò, ohun tí ẹ̀dá kò fẹ́ fojú ara rẹ̀ rí. Òkú ti di sao’ah nítorí pé, kò sí ẹni tí ó fẹ́ fojú ara rẹ̀ rí òkú.