1. Ìyẹn ni pé, kò sí ẹgbẹ́ tàbí ìdọ́gba láààrin ẹni tí ó ní òmìnira tí ó lè dá n̄ǹkan ṣe àti ẹrú aláìlágbára tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe.
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èèwọ̀ ẹ̀sìn ni fún ẹ̀dá láti fi àkàwé àti àfijọ lélẹ̀ fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah 74, Allāhu lè fi àkàwé ara Rẹ̀ lélẹ̀ fún ẹ̀dá nítorí kí ẹ̀dá lè mọ̀ pé Allāhu tóbi jùlọ.