ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
7 : 16

وَتَحۡمِلُ أَثۡقَالَكُمۡ إِلَىٰ بَلَدٖ لَّمۡ تَكُونُواْ بَٰلِغِيهِ إِلَّا بِشِقِّ ٱلۡأَنفُسِۚ إِنَّ رَبَّكُمۡ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ

Wọ́n sì ń ru àwọn ẹrù yín tó wúwo lọ sí ìlú kan tí ẹ kò lè dé àfi pẹ̀lú wàhálà ẹ̀mí. Dájúdájú Olúwa yín mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 16

وَٱلۡخَيۡلَ وَٱلۡبِغَالَ وَٱلۡحَمِيرَ لِتَرۡكَبُوهَا وَزِينَةٗۚ وَيَخۡلُقُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ

(Ó ṣẹ̀dá) ẹṣin, ìbaaka àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ nítorí kí ẹ lè gùn wọ́n. (Wọ́n tún jẹ́) ọ̀ṣọ́. Ó tún ń ṣẹ̀dá ohun tí ẹ kò mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 16

وَعَلَى ٱللَّهِ قَصۡدُ ٱلسَّبِيلِ وَمِنۡهَا جَآئِرٞۚ وَلَوۡ شَآءَ لَهَدَىٰكُمۡ أَجۡمَعِينَ

Allāhu l’Ó ń ṣàlàyé (’Islām) ọ̀nà tààrà. Àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wíwọ́ tún wà (lọ́tọ̀)[1]. Tí Ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìbá tọ́ gbogbo yín sí ọ̀nà (ẹ̀sìn ’Islām). info

1. Àwọn ọ̀nà wíwọ́ ni ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà, ẹ̀sìn yẹhudi àti ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄.

التفاسير:

external-link copy
10 : 16

هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗۖ لَّكُم مِّنۡهُ شَرَابٞ وَمِنۡهُ شَجَرٞ فِيهِ تُسِيمُونَ

Òun ni Ẹni tó ń sọ omi kalẹ̀ (fún yín) láti sánmọ̀. Mímu wà fún yín nínú rẹ̀. Igi ewéko tún ń wù jáde láti inú rẹ̀, tí ẹ fi ń bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 16

يُنۢبِتُ لَكُم بِهِ ٱلزَّرۡعَ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلنَّخِيلَ وَٱلۡأَعۡنَٰبَ وَمِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ

(Allāhu) tún ń fi (omi yìí) hu àwọn irúgbìn, igi òróró zaetūn, igi dàbínù, igi àjàrà àti gbogbo àwọn èso (yòókù) jáde fún yín. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 16

وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ وَٱلنُّجُومُ مُسَخَّرَٰتُۢ بِأَمۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ

Ó rọ òru, ọ̀sán, òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fún yín pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 16

وَمَا ذَرَأَ لَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهُۥٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّقَوۡمٖ يَذَّكَّرُونَ

Àti ohun tí Ó tún ṣẹ̀dá rẹ̀ fún yín lórí ilẹ̀, tí àwọn àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń lo ìrántí. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 16

وَهُوَ ٱلَّذِي سَخَّرَ ٱلۡبَحۡرَ لِتَأۡكُلُواْ مِنۡهُ لَحۡمٗا طَرِيّٗا وَتَسۡتَخۡرِجُواْ مِنۡهُ حِلۡيَةٗ تَلۡبَسُونَهَاۖ وَتَرَى ٱلۡفُلۡكَ مَوَاخِرَ فِيهِ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ

Òun ni Ẹni tí Ó rọ odò nítorí kí ẹ lè jẹ ẹran (ẹja) tútù àti nítorí kí ẹ lè mú n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ tí ẹ óò máa wọ̀ sára jáde láti inú (odò), - o sì máa rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí yóò máa la ojú omi kọjá lọ bọ̀ - àti nítorí kí ẹ lè wá nínú àwọn oore àjùlọ Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu). info
التفاسير: