1. Àwọn n̄ǹkan tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - dá fún dídá ojú ọ̀nà mọ̀ wọ̀nyí dúró fún rírína rí ojú ọ̀nà, yálà ní alẹ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tàbí ní ọ̀sán pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ òòrùn àti àwọn atọ́ka òpópónà.
1. Allāhu pe àwọn òrìṣà ní òkú nítorí pé, ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú, ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, ẹni tí kò lè ríran, ẹni tí kò lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́ ni ipò tí gbogbo ère òrìṣà wà.
1. Kíyè sí i! Kò sí ìtakora láààrin āyah yìí àti sūrah an-Najm; 53:38. Āyah àkọ́kọ́ ń sọ nípa ìpín ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa wà fún onísábàbí iṣẹ́-aburú àti onísábàbí ìṣìnà. Ìyẹn ni pé, bí ìyà ṣe wà fún oníṣẹ́-aburú bẹ́ẹ̀ náà ni ìyà wà fún onísábàbí rẹ̀. Ní ti āyah ti sūrah an-Najm, ò ń sọ nípa bí kò ṣe níí sí àǹfààní fún ẹnikẹ́ni láti gbé àpapọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lọ́rùn rẹ̀ fún ẹlòmíìràn ní Ọjọ́ ẹ̀san. Nítorí náà, àròpọ̀ iṣẹ́ tí ẹ̀dá ṣe àti iṣẹ́ tí ó ṣe sábàbí rẹ̀ ló máa wà lọ́rùn rẹ̀, yálà ó jẹ́ iṣẹ́ rere tàbí iṣẹ́ aburú. Kò sì níí rí alábàárù-ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ ọrùn rẹ̀. Ẹ tún wo sūrah al-‘ankabūt; 29:12 àti 13.