1. “ahlu-ththikr” (ìtúmọ̀ “àwọn oníràn-ántí / àwọn tí A sọ ìrántí kalẹ̀ fún).
1. Orúkọ tí wọ́n ń pe àlàyé tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe lórí al-Ƙur’ān ni “hadīth nabawiy” tàbí “sunnatu-rrọsūl” - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - . Ìmísí ni òhun náà nítorí pé, kì í fi ìfẹ́-inú rẹ̀ sọ̀rọ̀.
1. “‘Alā takawwuf” nínú āyah yìí tún túmọ̀ sí pé, “Tàbí (Allāhu) kò lè máa gbá wọn mú pẹ̀lú ẹ̀rù tí ó máa ti wà lára wọn nípa irú ìyà wo ni Allāhu máa fi jẹ wọ́n, tàbí irú àdánwò wo ni Ó máa dẹ sí wọn.”.
1. Ìyẹn ni pé, ní àárọ̀ láààrin ìgbà tí òòrùn bá yọ ní ìlà òòrùn títí di àsìkò òòrùn kàntàrí, òòji n̄ǹkan máa tẹ̀ sí agbègbè ìwọ̀ òòrùn ní orí ilẹ̀. Bákan náà, níkété tí òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí òòrùn máa wọ̀ ní ìwọ̀ òòrùn, òòji n̄ǹkan máa tẹ̀ sí agbègbè ìlà òòrùn ní orí ilẹ̀. Wàyí o, ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, ó sọ pé, “Títẹ̀ tí òòji gbogbo n̄ǹkan ń tẹ̀ sí ọ̀tún àti òsì ló ń dúró fún ìforíkanlẹ̀ wọn fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - . (Ƙurtubiy)
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah ar-Ra‘d; 13:15.
1. Ìyẹn ni pé, Allāhu nìkan ṣoso ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.