ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
111 : 16

۞ يَوۡمَ تَأۡتِي كُلُّ نَفۡسٖ تُجَٰدِلُ عَن نَّفۡسِهَا وَتُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ

(Rántí) Ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò dé tí yóò máa rojọ́ gbe ara rẹ̀. A ó sì san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́; wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn. info
التفاسير:

external-link copy
112 : 16

وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا قَرۡيَةٗ كَانَتۡ ءَامِنَةٗ مُّطۡمَئِنَّةٗ يَأۡتِيهَا رِزۡقُهَا رَغَدٗا مِّن كُلِّ مَكَانٖ فَكَفَرَتۡ بِأَنۡعُمِ ٱللَّهِ فَأَذَٰقَهَا ٱللَّهُ لِبَاسَ ٱلۡجُوعِ وَٱلۡخَوۡفِ بِمَا كَانُواْ يَصۡنَعُونَ

Allāhu fi àkàwé lélẹ̀ nípa ìlú kan, tí ó jẹ́ (ìlú) ààbò àti ìfàyàbalẹ̀, tí arísìkí rẹ̀ ń tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ ní púpọ̀ ní gbogbo àyè. Àmọ́ (wọ́n) ṣe àìmoore sí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ìyà ebi àti ìpáyà tọ́ wò nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
113 : 16

وَلَقَدۡ جَآءَهُمۡ رَسُولٞ مِّنۡهُمۡ فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَهُمۡ ظَٰلِمُونَ

Òjíṣẹ́ kúkú ti dé bá wọn láààrin ara wọn. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ọwọ́ ìyà bà wọ́n. Alábòsí sì ni wọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
114 : 16

فَكُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ حَلَٰلٗا طَيِّبٗا وَٱشۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ

Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín ní n̄ǹkan ẹ̀tọ́, tó dára. Kí ẹ sì dúpẹ́ oore Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
115 : 16

إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةَ وَٱلدَّمَ وَلَحۡمَ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦۖ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ

Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fún yín ni ẹran òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tó yàtọ́ sí “Allāhu”. Ṣùgbọ́n ẹni tí ìnira (ebi) bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀), tí kì í ṣe ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
116 : 16

وَلَا تَقُولُواْ لِمَا تَصِفُ أَلۡسِنَتُكُمُ ٱلۡكَذِبَ هَٰذَا حَلَٰلٞ وَهَٰذَا حَرَامٞ لِّتَفۡتَرُواْ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ لَا يُفۡلِحُونَ

Ẹ má ṣe sọ nípa ohun tí ahọ́n yín ròyìn ní irọ́ pé: “Èyí ni ẹ̀tọ́, èyí sì ni èèwọ̀” nítorí kí ẹ lè dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Dájúdájú àwọn tó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè. info
التفاسير:

external-link copy
117 : 16

مَتَٰعٞ قَلِيلٞ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

Ìgbádùn ayé bín-íntín (lè wà fún wọn, àmọ́) ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn (ní ọ̀run). info
التفاسير:

external-link copy
118 : 16

وَعَلَى ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا مَا قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ مِن قَبۡلُۖ وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ

Àti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi.[1] A kò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. info

1. Ìyẹn nínú sūrah an-Nisā’; 4:160 - 161.

التفاسير: