1. Àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n àlùjànnú máa ń gbé ara wọn gunra wọn láti lè súnmọ́ etí sánmọ̀ ilé ayé. Bí wọ́n bá bá àwọn mọlāika lórí àwọn ìro kan tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí wọn, wọ́n máa jí i gbọ́.
1. Àwọn n̄ǹkan mìíràn bíi àwọn sánmọ̀, àwọn ilẹ̀, àwọn mọlāika àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
1. Gbígba ọ̀tún wọlé sí ni lára ni pé, wọ́n ń lo orúkọ ’Islām láti fi pe àwọn ènìyàn lọ síbi ìṣẹbọ dípò mímú Allāhu ní Ọ̀kan ṣoṣo.
1. Bẹ̀rẹ̀ láti āyah 100 títí dé āyah 113, ó ti hàn kedere pé: (ìkíní) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni àkọ́bí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a -; (ìkejì) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni ẹni tí Allāhu Ẹlẹ́dàá pa láṣẹ pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - pa láti fi jọ́sìn fún Òun; (ìkẹta) Kò sí ohun tó jẹmọ́ ẹ̀jẹ́ àti ìmúṣẹ ẹ̀jẹ́ nínú àlá àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà; (ìkẹrin) Ìkíní kejì àwọn ọmọ méjèèjì náà ni ẹni ìbùkún.
1. Ìyẹn ni pé, nígbà tí ọkọ̀ ojú-omi fẹ́ yí dànù láààrin agbami odò nítorí èrò àkúnfàya, ọ̀rọ̀ jẹmọ́ kí ẹnì kan kúrò nínú rẹ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wọn máa bá omi lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe ƙur‘ah.