ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
52 : 37

يَقُولُ أَءِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُصَدِّقِينَ

tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde? info
التفاسير:

external-link copy
53 : 37

أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَدِينُونَ

Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?” info
التفاسير:

external-link copy
54 : 37

قَالَ هَلۡ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ

Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?” info
التفاسير:

external-link copy
55 : 37

فَٱطَّلَعَ فَرَءَاهُ فِي سَوَآءِ ٱلۡجَحِيمِ

Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm. info
التفاسير:

external-link copy
56 : 37

قَالَ تَٱللَّهِ إِن كِدتَّ لَتُرۡدِينِ

Ó (sì) sọ pé: “Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán. info
التفاسير:

external-link copy
57 : 37

وَلَوۡلَا نِعۡمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ

Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná. info
التفاسير:

external-link copy
58 : 37

أَفَمَا نَحۡنُ بِمَيِّتِينَ

Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí? info
التفاسير:

external-link copy
59 : 37

إِلَّا مَوۡتَتَنَا ٱلۡأُولَىٰ وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ

Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà. info
التفاسير:

external-link copy
60 : 37

إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ

Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.” info
التفاسير:

external-link copy
61 : 37

لِمِثۡلِ هَٰذَا فَلۡيَعۡمَلِ ٱلۡعَٰمِلُونَ

Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ. info
التفاسير:

external-link copy
62 : 37

أَذَٰلِكَ خَيۡرٞ نُّزُلًا أَمۡ شَجَرَةُ ٱلزَّقُّومِ

Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)? info
التفاسير:

external-link copy
63 : 37

إِنَّا جَعَلۡنَٰهَا فِتۡنَةٗ لِّلظَّٰلِمِينَ

Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí. info
التفاسير:

external-link copy
64 : 37

إِنَّهَا شَجَرَةٞ تَخۡرُجُ فِيٓ أَصۡلِ ٱلۡجَحِيمِ

Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm. info
التفاسير:

external-link copy
65 : 37

طَلۡعُهَا كَأَنَّهُۥ رُءُوسُ ٱلشَّيَٰطِينِ

Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n. info
التفاسير:

external-link copy
66 : 37

فَإِنَّهُمۡ لَأٓكِلُونَ مِنۡهَا فَمَالِـُٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ

Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Wọ́n sì máa jẹ ẹ́ ní àjẹyo bámúbámú. info
التفاسير:

external-link copy
67 : 37

ثُمَّ إِنَّ لَهُمۡ عَلَيۡهَا لَشَوۡبٗا مِّنۡ حَمِيمٖ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu àwọnúwẹ̀jẹ̀ olómi gbígbóná tó gbóná parí lé e lórí. info
التفاسير:

external-link copy
68 : 37

ثُمَّ إِنَّ مَرۡجِعَهُمۡ لَإِلَى ٱلۡجَحِيمِ

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm. info
التفاسير:

external-link copy
69 : 37

إِنَّهُمۡ أَلۡفَوۡاْ ءَابَآءَهُمۡ ضَآلِّينَ

Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà. info
التفاسير:

external-link copy
70 : 37

فَهُمۡ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ يُهۡرَعُونَ

Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn. info
التفاسير:

external-link copy
71 : 37

وَلَقَدۡ ضَلَّ قَبۡلَهُمۡ أَكۡثَرُ ٱلۡأَوَّلِينَ

Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn. info
التفاسير:

external-link copy
72 : 37

وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ

Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn. info
التفاسير:

external-link copy
73 : 37

فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُنذَرِينَ

Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí. info
التفاسير:

external-link copy
74 : 37

إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo). info
التفاسير:

external-link copy
75 : 37

وَلَقَدۡ نَادَىٰنَا نُوحٞ فَلَنِعۡمَ ٱلۡمُجِيبُونَ

Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè. info
التفاسير:

external-link copy
76 : 37

وَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ

A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà. info
التفاسير: