ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
154 : 37

مَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ

Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí? info
التفاسير:

external-link copy
155 : 37

أَفَلَا تَذَكَّرُونَ

Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni? info
التفاسير:

external-link copy
156 : 37

أَمۡ لَكُمۡ سُلۡطَٰنٞ مُّبِينٞ

Tàbí ẹ ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ ni? info
التفاسير:

external-link copy
157 : 37

فَأۡتُواْ بِكِتَٰبِكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo. info
التفاسير:

external-link copy
158 : 37

وَجَعَلُواْ بَيۡنَهُۥ وَبَيۡنَ ٱلۡجِنَّةِ نَسَبٗاۚ وَلَقَدۡ عَلِمَتِ ٱلۡجِنَّةُ إِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ

Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni. info
التفاسير:

external-link copy
159 : 37

سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ

Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
160 : 37

إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo). info
التفاسير:

external-link copy
161 : 37

فَإِنَّكُمۡ وَمَا تَعۡبُدُونَ

Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu), info
التفاسير:

external-link copy
162 : 37

مَآ أَنتُمۡ عَلَيۡهِ بِفَٰتِنِينَ

ẹ kò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà info
التفاسير:

external-link copy
163 : 37

إِلَّا مَنۡ هُوَ صَالِ ٱلۡجَحِيمِ

àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm. info
التفاسير:

external-link copy
164 : 37

وَمَا مِنَّآ إِلَّا لَهُۥ مَقَامٞ مَّعۡلُومٞ

Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
165 : 37

وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلصَّآفُّونَ

Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ni. info
التفاسير:

external-link copy
166 : 37

وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلۡمُسَبِّحُونَ

Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu). info
التفاسير:

external-link copy
167 : 37

وَإِن كَانُواْ لَيَقُولُونَ

Wọ́n kúkú ń wí pé: info
التفاسير:

external-link copy
168 : 37

لَوۡ أَنَّ عِندَنَا ذِكۡرٗا مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ

“Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́, info
التفاسير:

external-link copy
169 : 37

لَكُنَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).” info
التفاسير:

external-link copy
170 : 37

فَكَفَرُواْ بِهِۦۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ

Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
171 : 37

وَلَقَدۡ سَبَقَتۡ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
172 : 37

إِنَّهُمۡ لَهُمُ ٱلۡمَنصُورُونَ

Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún. info
التفاسير:

external-link copy
173 : 37

وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ ٱلۡغَٰلِبُونَ

Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí. info
التفاسير:

external-link copy
174 : 37

فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
175 : 37

وَأَبۡصِرۡهُمۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ

Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò. info
التفاسير:

external-link copy
176 : 37

أَفَبِعَذَابِنَا يَسۡتَعۡجِلُونَ

Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú? info
التفاسير:

external-link copy
177 : 37

فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمۡ فَسَآءَ صَبَاحُ ٱلۡمُنذَرِينَ

Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí gbàgede wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún. info
التفاسير:

external-link copy
178 : 37

وَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ

Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná. info
التفاسير:

external-link copy
179 : 37

وَأَبۡصِرۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ

Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò. info
التفاسير:

external-link copy
180 : 37

سُبۡحَٰنَ رَبِّكَ رَبِّ ٱلۡعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ

Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa (tó ni) agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀). info
التفاسير:

external-link copy
181 : 37

وَسَلَٰمٌ عَلَى ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́ info
التفاسير:

external-link copy
182 : 37

وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير: