ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
127 : 37

فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ

Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná. info
التفاسير:

external-link copy
128 : 37

إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo). info
التفاسير:

external-link copy
129 : 37

وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ

A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn. info
التفاسير:

external-link copy
130 : 37

سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِلۡ يَاسِينَ

Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās. info
التفاسير:

external-link copy
131 : 37

إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere). info
التفاسير:

external-link copy
132 : 37

إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
133 : 37

وَإِنَّ لُوطٗا لَّمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
134 : 37

إِذۡ نَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ

(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là. info
التفاسير:

external-link copy
135 : 37

إِلَّا عَجُوزٗا فِي ٱلۡغَٰبِرِينَ

Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:171.

التفاسير:

external-link copy
136 : 37

ثُمَّ دَمَّرۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ

Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run. info
التفاسير:

external-link copy
137 : 37

وَإِنَّكُمۡ لَتَمُرُّونَ عَلَيۡهِم مُّصۡبِحِينَ

Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀ info
التفاسير:

external-link copy
138 : 37

وَبِٱلَّيۡلِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ

àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni? info
التفاسير:

external-link copy
139 : 37

وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
140 : 37

إِذۡ أَبَقَ إِلَى ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ

(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún (fún èrò). info
التفاسير:

external-link copy
141 : 37

فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُدۡحَضِينَ

Ó sì bá wọn ṣe kúríà papọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí kúrìá já.[1] info

1. Ìyẹn ni pé, nígbà tí ọkọ̀ ojú-omi fẹ́ yí dànù láààrin agbami odò nítorí èrò àkúnfàya, ọ̀rọ̀ jẹmọ́ kí ẹnì kan kúrò nínú rẹ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wọn máa bá omi lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe ƙur‘ah.

التفاسير:

external-link copy
142 : 37

فَٱلۡتَقَمَهُ ٱلۡحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٞ

Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi. info
التفاسير:

external-link copy
143 : 37

فَلَوۡلَآ أَنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُسَبِّحِينَ

Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu, info
التفاسير:

external-link copy
144 : 37

لَلَبِثَ فِي بَطۡنِهِۦٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ

dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde. info
التفاسير:

external-link copy
145 : 37

۞ فَنَبَذۡنَٰهُ بِٱلۡعَرَآءِ وَهُوَ سَقِيمٞ

Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera. info
التفاسير:

external-link copy
146 : 37

وَأَنۢبَتۡنَا عَلَيۡهِ شَجَرَةٗ مِّن يَقۡطِينٖ

A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó. info
التفاسير:

external-link copy
147 : 37

وَأَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ مِاْئَةِ أَلۡفٍ أَوۡ يَزِيدُونَ

A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.[1] info

1. Ọ̀kẹ́ márùn-ún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000).

التفاسير:

external-link copy
148 : 37

فَـَٔامَنُواْ فَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٖ

Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
149 : 37

فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَلِرَبِّكَ ٱلۡبَنَاتُ وَلَهُمُ ٱلۡبَنُونَ

Bi wọ́n léèrè wò pé: “Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin? info
التفاسير:

external-link copy
150 : 37

أَمۡ خَلَقۡنَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ إِنَٰثٗا وَهُمۡ شَٰهِدُونَ

Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?” info
التفاسير:

external-link copy
151 : 37

أَلَآ إِنَّهُم مِّنۡ إِفۡكِهِمۡ لَيَقُولُونَ

Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: info
التفاسير:

external-link copy
152 : 37

وَلَدَ ٱللَّهُ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ

“Allāhu bímọ.” Dájúdájú òpùrọ́ sì ni wọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
153 : 37

أَصۡطَفَى ٱلۡبَنَاتِ عَلَى ٱلۡبَنِينَ

Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni? info
التفاسير: