1. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n tì wà ní ipò mùsùlùmí lórí sunnah Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - , tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tún dé bá wọn láyé, tí wọ́n sì gbà fún sunnah tirẹ̀ náà. Wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.
1. “Hidāyah” túmọ̀ sí ìwọ̀nyí: (1) Ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn ’Islām, ṣíṣí ọkàn ẹ̀dá payá fún gbígba ẹ̀sìn ’Islām, fífi al-Ƙur’ān àti sunnah ṣàlàyé ìmọ̀nà sí ọ̀nà tààrà ’Islām àti títọ́ka ènìyàn sí ibì kan tàbí fífi ojú-ọ̀nà kan mọ ènìyàn.