ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
78 : 28

قَالَ إِنَّمَآ أُوتِيتُهُۥ عَلَىٰ عِلۡمٍ عِندِيٓۚ أَوَلَمۡ يَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ قَدۡ أَهۡلَكَ مِن قَبۡلِهِۦ مِنَ ٱلۡقُرُونِ مَنۡ هُوَ أَشَدُّ مِنۡهُ قُوَّةٗ وَأَكۡثَرُ جَمۡعٗاۚ وَلَا يُسۡـَٔلُ عَن ذُنُوبِهِمُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ

Ó wí pé: “Dájúdájú wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ tó ń bẹ lọ́dọ̀ mi ni.”[1] Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ti parun nínú àwọn ìran tó ṣíwájú rẹ̀, ẹni tí ó lágbára jù ú lọ, tí ó sì ní àkójọ ọrọ̀ jù ú lọ? A ò sì níí bi àwọn arúfin léèrè (ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó kúkú ti wà ní àkọsílẹ̀.) info

1. Ìyẹn ni pé, òun mọ̀ ọ́ ṣe ni ti tòun fi gún. Dípò kí ó moore sí Allāhu, kí ó dúpẹ́ fún Un, kí ó sì mọ̀ pé Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un ni nínú kádàrá Rẹ̀.

التفاسير:

external-link copy
79 : 28

فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ فِي زِينَتِهِۦۖ قَالَ ٱلَّذِينَ يُرِيدُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا يَٰلَيۡتَ لَنَا مِثۡلَ مَآ أُوتِيَ قَٰرُونُ إِنَّهُۥ لَذُو حَظٍّ عَظِيمٖ

Ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Àwọn tó ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí sì wí pé: “Háà! Kí á sì ní irú ohun tí wọ́n fún Ƙọ̄rūn. Dájúdájú ó ní ìpín ńlá nínú oore.” info
التفاسير:

external-link copy
80 : 28

وَقَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ وَيۡلَكُمۡ ثَوَابُ ٱللَّهِ خَيۡرٞ لِّمَنۡ ءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗاۚ وَلَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ٱلصَّٰبِرُونَ

Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ sọ pé: “Ègbé ni fún yín! Ẹ̀san Allāhu lóore jùlọ fún ẹni tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì sí ẹni tí ó máa rí (ẹ̀san náà) gbà àfi àwọn onísùúrù.” info
التفاسير:

external-link copy
81 : 28

فَخَسَفۡنَا بِهِۦ وَبِدَارِهِ ٱلۡأَرۡضَ فَمَا كَانَ لَهُۥ مِن فِئَةٖ يَنصُرُونَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُنتَصِرِينَ

Nítorí náà, A jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé òun àti ilé rẹ̀ mì. Kò ní ìjọ kan tí ó lè ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì sí nínú àwọn tó lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́. info
التفاسير:

external-link copy
82 : 28

وَأَصۡبَحَ ٱلَّذِينَ تَمَنَّوۡاْ مَكَانَهُۥ بِٱلۡأَمۡسِ يَقُولُونَ وَيۡكَأَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ وَيَقۡدِرُۖ لَوۡلَآ أَن مَّنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡنَا لَخَسَفَ بِنَاۖ وَيۡكَأَنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلۡكَٰفِرُونَ

Àwọn tó ń rankàn ipò rẹ̀ ní àná sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ṣé ẹ rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu kẹ́ wa ni, ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé àwa náà mì ni. Ṣé ẹ rí i pé àwọn aláìmoore kò níí jèrè.” info
التفاسير:

external-link copy
83 : 28

تِلۡكَ ٱلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ نَجۡعَلُهَا لِلَّذِينَ لَا يُرِيدُونَ عُلُوّٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فَسَادٗاۚ وَٱلۡعَٰقِبَةُ لِلۡمُتَّقِينَ

Ilé Ìkẹ́yìn yẹn, A máa fi fún àwọn tí kò fẹ́ máa ṣe ìgbéraga àti ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). info
التفاسير:

external-link copy
84 : 28

مَن جَآءَ بِٱلۡحَسَنَةِ فَلَهُۥ خَيۡرٞ مِّنۡهَاۖ وَمَن جَآءَ بِٱلسَّيِّئَةِ فَلَا يُجۡزَى ٱلَّذِينَ عَمِلُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ إِلَّا مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Ẹnikẹ́ni tí ó bá dé pẹ̀lú iṣẹ́ rere, tirẹ̀ ni rere tó lóore ju èyí tó mú wá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì dé pẹ̀lú iṣẹ́ aburú, A kò níí san àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san kan àfi ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. info
التفاسير: