ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
6 : 28

وَنُمَكِّنَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَنُرِيَ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَجُنُودَهُمَا مِنۡهُم مَّا كَانُواْ يَحۡذَرُونَ

A (fẹ́) gbà wọ́n láàyè lórí ilẹ̀. Láti ara wọn, A sì (fẹ́) fi han Fir‘aon àti Hāmọ̄n pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì ohun tí wọ́n ń ṣọ́ra fún lára wọn. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 28

وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ أُمِّ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَرۡضِعِيهِۖ فَإِذَا خِفۡتِ عَلَيۡهِ فَأَلۡقِيهِ فِي ٱلۡيَمِّ وَلَا تَخَافِي وَلَا تَحۡزَنِيٓۖ إِنَّا رَآدُّوهُ إِلَيۡكِ وَجَاعِلُوهُ مِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

A sì ránṣẹ́ sí ìyá (Ànábì) Mūsā pé: “Fún un ní ọmú mu. Tí o bá sì ń páyà lórí rẹ̀, jù ú sínú odò. Má ṣe bẹ̀rù. Má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú Àwa máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. A ó sì ṣe é ní ara àwọn Òjíṣẹ́.” info
التفاسير:

external-link copy
8 : 28

فَٱلۡتَقَطَهُۥٓ ءَالُ فِرۡعَوۡنَ لِيَكُونَ لَهُمۡ عَدُوّٗا وَحَزَنًاۗ إِنَّ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَجُنُودَهُمَا كَانُواْ خَٰطِـِٔينَ

Nígbà náà, àwọn ènìyàn Fir‘aon rí i he nítorí kí ó lè jẹ́ ọ̀tá àti ìbànújẹ́ fún wọn. Dájúdájú Fir‘aon, Hāmọ̄n àti àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì, wọ́n jẹ́ aláṣìṣe. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 28

وَقَالَتِ ٱمۡرَأَتُ فِرۡعَوۡنَ قُرَّتُ عَيۡنٖ لِّي وَلَكَۖ لَا تَقۡتُلُوهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوۡ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدٗا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ

Ìyàwó Fir‘aon wí pé: “Ìtutù-ojú ni (ọmọ yìí) fún èmi àti ìwọ. Ẹ má ṣe pa á. Ó lè jẹ́ pé ó máa ṣe wá ní àǹfààní tàbí kí a fi ṣe ọmọ.” Wọn kò sì fura. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 28

وَأَصۡبَحَ فُؤَادُ أُمِّ مُوسَىٰ فَٰرِغًاۖ إِن كَادَتۡ لَتُبۡدِي بِهِۦ لَوۡلَآ أَن رَّبَطۡنَا عَلَىٰ قَلۡبِهَا لِتَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Ọkàn ìyá (Ànábì) Mūsā pami (lórí ọ̀rọ̀ Mūsā, kò sì rí n̄ǹkan mìíràn rò mọ́ tayọ rẹ̀) ó kúkú fẹ́ẹ̀ ṣàfi hàn rẹ̀ (pé ọmọ òun ni nígbà tí wọ́n pè é dé ọ̀dọ̀ Fir‘aon) tí kò bá jẹ́ pé A kì í lọ́kàn nítorí kí ó lè wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 28

وَقَالَتۡ لِأُخۡتِهِۦ قُصِّيهِۖ فَبَصُرَتۡ بِهِۦ عَن جُنُبٖ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ

Ó sì sọ fún arábìnrin rẹ̀ pé: “Tọ ipa rẹ̀ lọ.” Ó sì ń wò ó láti ibi tó jìnnà. Wọn kò sì fura (sí i). info
التفاسير:

external-link copy
12 : 28

۞ وَحَرَّمۡنَا عَلَيۡهِ ٱلۡمَرَاضِعَ مِن قَبۡلُ فَقَالَتۡ هَلۡ أَدُلُّكُمۡ عَلَىٰٓ أَهۡلِ بَيۡتٖ يَكۡفُلُونَهُۥ لَكُمۡ وَهُمۡ لَهُۥ نَٰصِحُونَ

A kò sì jẹ́ kí ó mu ọyàn (mìíràn) ṣíwájú (tìyá rẹ̀.) (Arábìnrin rẹ̀ sì) wí pé: “Ṣé kí èmi júwe yín sí ará ilé kan tí ó máa gbà á tọ́ fún yín? Wọn yó sì jẹ́ olùtọ́jú rẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
13 : 28

فَرَدَدۡنَٰهُ إِلَىٰٓ أُمِّهِۦ كَيۡ تَقَرَّ عَيۡنُهَا وَلَا تَحۡزَنَ وَلِتَعۡلَمَ أَنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ

A sì dá a padà sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ nítorí kí ojú rẹ̀ lè tutù (fún ìdùnnú) àti nítorí kí ó má baà banújẹ́. Àti pé nítorí kí ó lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu, òdodo ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀. info
التفاسير: