ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
53 : 28

وَإِذَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِهِۦٓ إِنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّنَآ إِنَّا كُنَّا مِن قَبۡلِهِۦ مُسۡلِمِينَ

Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọ́n á sọ pé: “A gbà á gbọ́. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa. Dájúdájú àwa ti jẹ́ mùsùlùmí ṣíwájú rẹ̀.”[1] info

1. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n tì wà ní ipò mùsùlùmí lórí sunnah Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - , tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tún dé bá wọn láyé, tí wọ́n sì gbà fún sunnah tirẹ̀ náà. Wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.

التفاسير: