ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
98 : 10

فَلَوۡلَا كَانَتۡ قَرۡيَةٌ ءَامَنَتۡ فَنَفَعَهَآ إِيمَٰنُهَآ إِلَّا قَوۡمَ يُونُسَ لَمَّآ ءَامَنُواْ كَشَفۡنَا عَنۡهُمۡ عَذَابَ ٱلۡخِزۡيِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٖ

Kí ó sì jẹ́ pé ìlú kàn gbàgbọ́ (lásìkò ìsọ̀kalẹ̀ ìyà), kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì ṣe é ní àǹfààní (kò kúkú sí) àfi ìjọ (Ànábì) Yūnus (nítorí pé), nígbà tí wọ́n gbàgbọ́, A mú àbùkù ìyà kúrò fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé. A sì jẹ́ kí wọ́n jẹ ìgbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
99 : 10

وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ لَأٓمَنَ مَن فِي ٱلۡأَرۡضِ كُلُّهُمۡ جَمِيعًاۚ أَفَأَنتَ تُكۡرِهُ ٱلنَّاسَ حَتَّىٰ يَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ

Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, gbogbo àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá ìbá gbàgbọ́. Nítorí náà, ṣé ìwọ lo máa jẹ àwọn ènìyàn nípá títí wọn yóò fi di onígbàgbọ́ òdodo ni? info
التفاسير:

external-link copy
100 : 10

وَمَا كَانَ لِنَفۡسٍ أَن تُؤۡمِنَ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَيَجۡعَلُ ٱلرِّجۡسَ عَلَى ٱلَّذِينَ لَا يَعۡقِلُونَ

Ẹ̀mí kan kò lè gbàgbọ́ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ó sì máa fi ìyà jẹ àwọn tí kò ṣe làákàyè.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah at-Taobah; 9:13.

التفاسير:

external-link copy
101 : 10

قُلِ ٱنظُرُواْ مَاذَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَمَا تُغۡنِي ٱلۡأٓيَٰتُ وَٱلنُّذُرُ عَن قَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ

Sọ pé: “Ẹ wòye sí n̄ǹkan tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn āyah àti ìkìlọ̀ kò sì níí rọ ìjọ aláìgbàgbọ́ lọ́rọ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
102 : 10

فَهَلۡ يَنتَظِرُونَ إِلَّا مِثۡلَ أَيَّامِ ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلِهِمۡۚ قُلۡ فَٱنتَظِرُوٓاْ إِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُنتَظِرِينَ

Nítorí náà, ṣé wọ́n tún ń retí (n̄ǹkan mìíràn) ni bí kò ṣe (ìparun) irú ti ọjọ́ àwọn tó ré kọjá lọ ṣíwájú wọn. Sọ pé: “Ẹ máa retí nígbà náà. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.” info
التفاسير:

external-link copy
103 : 10

ثُمَّ نُنَجِّي رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ كَذَٰلِكَ حَقًّا عَلَيۡنَا نُنجِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Lẹ́yìn náà, A óò gba àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn tó gbàgbọ́ lódodo là. Báyẹn ní ó ṣe jẹ́ ojúṣe Wa láti gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là. info
التفاسير:

external-link copy
104 : 10

قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمۡ فِي شَكّٖ مِّن دِينِي فَلَآ أَعۡبُدُ ٱلَّذِينَ تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِنۡ أَعۡبُدُ ٱللَّهَ ٱلَّذِي يَتَوَفَّىٰكُمۡۖ وَأُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ẹ̀sìn mi. Nígbà náà, èmi kò níí jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣùgbọ́n èmi yóò máa jọ́sìn fún Allāhu, Ẹni tí Ó máa gba ẹ̀mí yín. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
105 : 10

وَأَنۡ أَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفٗا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ

(Wọ́n tún pa mí láṣẹ pé): “Dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn.[1] Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ. info

1. “Hanīf”; olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Òun ni ẹni tí ó yàgò fún gbogbo ìṣìnà àti ẹ̀sìnkẹ́sìn, tí ó wá dúró déédé sínú ìmọ̀nà ’Islām nìkan ṣoṣo. Ipò tí gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - wà nìyẹn nínú ’Islām.

التفاسير:

external-link copy
106 : 10

وَلَا تَدۡعُ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَۖ فَإِن فَعَلۡتَ فَإِنَّكَ إِذٗا مِّنَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Àti pé má ṣe pè lẹ́yìn Allāhu n̄ǹkan tí kò lè ṣe ọ́ ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá ọ. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà, dájúdájú ìwọ ti wà nínú àwọn alábòsí.” info
التفاسير: