1. Gbólóhùn tí Fir‘aon sọ yìí kò wúlò fún un torí pé, ó ti rí ikú ṣíwájú kí ó tó gbàgbọ́.
1. Ìyẹn ni pé, àwọn yẹ̀húdí ní àpapọ̀ gbàgbọ́ nínú àwọn āyah àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbédìde Ànábì ìkẹ́yìn nínú at-Taorāh, àmọ́ nígbà tí òdodo náà padà ṣẹlẹ̀, wọ́n bá yapa-ẹnu lórí rẹ̀ ní ti ìlàra àti àbòsí.
1. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ gba ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ àwọn onítírà, àmọ́ láti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé, Allāhu ló fi iṣẹ́ rán gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò sì níí sí ìtakora nínú àwọn iṣẹ́ náà.