ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

external-link copy
105 : 10

وَأَنۡ أَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفٗا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ

(Wọ́n tún pa mí láṣẹ pé): “Dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn.[1] Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ. info

1. “Hanīf”; olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Òun ni ẹni tí ó yàgò fún gbogbo ìṣìnà àti ẹ̀sìnkẹ́sìn, tí ó wá dúró déédé sínú ìmọ̀nà ’Islām nìkan ṣoṣo. Ipò tí gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - wà nìyẹn nínú ’Islām.

التفاسير: