Ẹ̀yin kọ́ lẹ pa wọ́n, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó pa wọ́n. Àti pé ìwọ kọ́ lo jùkò nígbà tí o jùkò, àmọ́ dájúdájú Allāhu l’Ó jùkò[1] nítorí kí (Allāhu) lè fi àmìwò dáadáa kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
1. Ìyẹn ni pé, àṣẹ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - tó ń bẹ lára òkò tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jù lu àwọn kèfèrí l’ó gba ẹ̀mí wọn.