Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọrọ̀ ogun. Sọ pé: “Ọrọ̀ ogun jẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì ṣe àtúnṣe n̄ǹkan tí ń bẹ láààrin yín. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi (ìyà) Allāhu ṣe ìrántí (fún wọn), ọkàn wọn yóò wárìrì, nígbà tí wọ́n bá sì ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn, wọn yóò lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.