《古兰经》译解 - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖。

external-link copy
17 : 8

فَلَمۡ تَقۡتُلُوهُمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ قَتَلَهُمۡۚ وَمَا رَمَيۡتَ إِذۡ رَمَيۡتَ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ رَمَىٰ وَلِيُبۡلِيَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ مِنۡهُ بَلَآءً حَسَنًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ

Ẹ̀yin kọ́ lẹ pa wọ́n, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó pa wọ́n. Àti pé ìwọ kọ́ lo jùkò nígbà tí o jùkò, àmọ́ dájúdájú Allāhu l’Ó jùkò[1] nítorí kí (Allāhu) lè fi àmìwò dáadáa kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀. info

1. Ìyẹn ni pé, àṣẹ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - tó ń bẹ lára òkò tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jù lu àwọn kèfèrí l’ó gba ẹ̀mí wọn.

التفاسير: