1. Kíyè sí i, òfin tó ṣe é ní èèwọ̀ fún ọkọ láti fi ẹ̀yìn ìyàwó rẹ̀ wé ẹ̀yìn ìyá rẹ̀, òfin náà l’ó ṣe é ní èèwọ̀ fún un láti fi wé ẹ̀yìn ìyá tó fún un ní ọyàn mú ní kékeré nígbà tí kò tí ì já l’ẹ́nu ọyàn.
1. Āyah yìí kò túmọ̀ sí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà lórí ilẹ̀ ayé tàbí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan. Wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ kò sì túmọ̀ sí sísọ Pàápàá Allāhu di púpọ̀ bí ẹ̀dá, kò sì túmọ̀ sí sísọ Allāhu di Ẹni tí kò níí wà lórí Ìtẹ́-Ọlá Rẹ̀ lókè sánmọ̀ keje, bí kò ṣe pé wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ ni pé, “Allāhu ń gbọ́ ohùn ẹ̀dá”, “Ó ń rí ẹ̀dá”, “Ó mọ ẹ̀dá”, “Ó ń ṣọ́ ẹ̀dá”. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Tọ̄hā; 20:46, sūrah at-Tọlāƙ; 65:12 àti sūrah al-Mulk; 67: 16 àti 17.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hujurọ̄t; 49:7.
1. Kíyè sí i! Ìtúmọ̀ “rūh” nínú āyah yìí ni ẹ̀rí òdodo, ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà. Àmọ́ ìtúmọ̀ “rūh” nínú sūrah an-Nisā’; 4:171, ìyẹn túmọ̀ sí ẹ̀mí tí Allāhu Ẹlẹ́dàá fi dá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Bákan náà, “minhu” tí ó wà pẹ̀lú “rūh” nínú àwọn āyah méjèèjì túmọ̀ sí pé, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni ẹ̀rí òdodo (ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà) àti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti wá.