Bản dịch ý nghĩa nội dung Qur'an - 约鲁巴语翻译 - 艾布·拉西麦·米卡依赖

Số trang:close

external-link copy
75 : 18

۞ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكَ إِنَّكَ لَن تَسۡتَطِيعَ مَعِيَ صَبۡرٗا

(Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé dájúdájú ìwọ kò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.” info
التفاسير:

external-link copy
76 : 18

قَالَ إِن سَأَلۡتُكَ عَن شَيۡءِۭ بَعۡدَهَا فَلَا تُصَٰحِبۡنِيۖ قَدۡ بَلَغۡتَ مِن لَّدُنِّي عُذۡرٗا

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí mo bá tún bi ọ́ nípa kiní kan lẹ́yìn rẹ̀, má ṣe bá mi rìn mọ́. Dájúdájú o ti mú àwáwí dé òpin lọ́dọ̀ mi.” info
التفاسير:

external-link copy
77 : 18

فَٱنطَلَقَا حَتَّىٰٓ إِذَآ أَتَيَآ أَهۡلَ قَرۡيَةٍ ٱسۡتَطۡعَمَآ أَهۡلَهَا فَأَبَوۡاْ أَن يُضَيِّفُوهُمَا فَوَجَدَا فِيهَا جِدَارٗا يُرِيدُ أَن يَنقَضَّ فَأَقَامَهُۥۖ قَالَ لَوۡ شِئۡتَ لَتَّخَذۡتَ عَلَيۡهِ أَجۡرٗا

Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú kan. Wọ́n tọrọ oúnjẹ lọ́dọ̀ àwọn ará ìlú náà. Wọ́n sì kọ̀ láti ṣe wọ́n ní àlejò. Àwọn méjèèjì sì bá ògiri kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ wó. (Kidr) sì gbé e dìde. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé o bá fẹ́, kí o sì gba owó-ọ̀yà lórí rẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
78 : 18

قَالَ هَٰذَا فِرَاقُ بَيۡنِي وَبَيۡنِكَۚ سَأُنَبِّئُكَ بِتَأۡوِيلِ مَا لَمۡ تَسۡتَطِع عَّلَيۡهِ صَبۡرًا

(Kidr) sọ pé: “Èyí ni òpínyà láààrin èmi àti ìwọ. Mo sì máa fún ọ ní ìtúmọ̀ ohun tí ìwọ kò lè ṣe sùúrù lórí rẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
79 : 18

أَمَّا ٱلسَّفِينَةُ فَكَانَتۡ لِمَسَٰكِينَ يَعۡمَلُونَ فِي ٱلۡبَحۡرِ فَأَرَدتُّ أَنۡ أَعِيبَهَا وَكَانَ وَرَآءَهُم مَّلِكٞ يَأۡخُذُ كُلَّ سَفِينَةٍ غَصۡبٗا

Ní ti ọkọ̀ ojú-omi, ó jẹ́ ti àwọn mẹ̀kúnnù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí omi. Mo sì fẹ́ láti fi àlébù kàn án (nítorí pé), ọba kan wà níwájú wọn tó ń gba gbogbo ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú ipá. info
التفاسير:

external-link copy
80 : 18

وَأَمَّا ٱلۡغُلَٰمُ فَكَانَ أَبَوَاهُ مُؤۡمِنَيۡنِ فَخَشِينَآ أَن يُرۡهِقَهُمَا طُغۡيَٰنٗا وَكُفۡرٗا

Ní ti ọmọdékùnrin náà, àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. A sì ń bẹ̀rù pé kí ó màa kó ìtayọ ẹnu-ààlà àti àìgbàgbọ́ bá àwọn méjèèjì.[1] info

1. Ìyẹn ni pé, òbí ń ṣẹ Allāhu níbi ìfẹ́ ọmọ nígbà tí òbí bá ń pọ̀n lẹ́yìn ọmọ burúkú. Aburú ńlá sì ni fún àwọn méjèèjì.

التفاسير:

external-link copy
81 : 18

فَأَرَدۡنَآ أَن يُبۡدِلَهُمَا رَبُّهُمَا خَيۡرٗا مِّنۡهُ زَكَوٰةٗ وَأَقۡرَبَ رُحۡمٗا

Nítorí náà, A fẹ́ kí Olúwa àwọn méjèèjì pààrọ̀ rẹ̀ fún wọn pẹ̀lú (èyí) tó lóore jù ú lọ tó máa jẹ́ ẹni mímọ́ jù ú lọ àti (èyí) tó máa jẹ́ ọmọ rere olújú-àánú sí (àwọn òbí rẹ̀) jù ú lọ. info
التفاسير:

external-link copy
82 : 18

وَأَمَّا ٱلۡجِدَارُ فَكَانَ لِغُلَٰمَيۡنِ يَتِيمَيۡنِ فِي ٱلۡمَدِينَةِ وَكَانَ تَحۡتَهُۥ كَنزٞ لَّهُمَا وَكَانَ أَبُوهُمَا صَٰلِحٗا فَأَرَادَ رَبُّكَ أَن يَبۡلُغَآ أَشُدَّهُمَا وَيَسۡتَخۡرِجَا كَنزَهُمَا رَحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَۚ وَمَا فَعَلۡتُهُۥ عَنۡ أَمۡرِيۚ ذَٰلِكَ تَأۡوِيلُ مَا لَمۡ تَسۡطِع عَّلَيۡهِ صَبۡرٗا

Nípa ti ògiri, ó jẹ́ ti àwọn ọmọdékùnrin, ọmọ òrukàn méjì kan nínú ìlú náà. Àpótí-ọrọ̀ kan sì ń bẹ fún àwọn méjèèjì lábẹ́ ògiri náà. Bàbá àwọn méjèèjì sì jẹ́ ẹni rere. Nítorí náà, Olúwa rẹ fẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà dáadáa (bá dúkìá náà), kí wọ́n sì hú dúkìá wọn jáde (kí ó lè jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Èmi kò dá a ṣe láti ọ̀dọ̀ ara mi; (Allāhu l’Ó pa mí láṣẹ rẹ̀). Ìyẹn ni ìtúmọ̀ ohun tí ìwọ kò lè ṣe sùúrù fún. info
التفاسير:

external-link copy
83 : 18

وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَن ذِي ٱلۡقَرۡنَيۡنِۖ قُلۡ سَأَتۡلُواْ عَلَيۡكُم مِّنۡهُ ذِكۡرًا

Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Thul-Ƙọrnaen. Sọ pé: “Mo máa mú ọ̀rọ̀ ìrántí wá fún yín nípa rẹ̀.” info
التفاسير: