قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ - ابو رحیمہ مائیکل

Al-Ah'koof

external-link copy
1 : 46

حمٓ

Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 46

تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ

Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 46

مَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَأَجَلٖ مُّسَمّٗىۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَمَّآ أُنذِرُواْ مُعۡرِضُونَ

A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa gbúnrí kúrò níbi ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 46

قُلۡ أَرَءَيۡتُم مَّا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُواْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ لَهُمۡ شِرۡكٞ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِۖ ٱئۡتُونِي بِكِتَٰبٖ مِّن قَبۡلِ هَٰذَآ أَوۡ أَثَٰرَةٖ مِّنۡ عِلۡمٍ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun tó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi tó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo.” info
التفاسير:

external-link copy
5 : 46

وَمَنۡ أَضَلُّ مِمَّن يَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَن لَّا يَسۡتَجِيبُ لَهُۥٓ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَهُمۡ عَن دُعَآئِهِمۡ غَٰفِلُونَ

Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tí ó ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹni tí kò lè jẹ́ ìpè rẹ̀ títí di Ọjọ́ Àjíǹde! Àti pé wọn kò ní òye sí pípè tí wọ́n ń pè wọ́n.[1] info

1. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn olùṣìnà jùlọ yìí ni àwọn nasọ̄rọ̄ tí wọ́n ń pe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - pẹ̀lú àwáwí pé ó wà láàyè nínú sánmọ̀, àmọ́ tí wọn kò mọ̀ pé ó kàn wà nínú sánmọ̀ ni, kò lè gbọ́ ìpè wọn áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa jẹ́pè wọn. Allāhu nìkan ṣoṣo l’Ó lè jẹ́pè àwọn ẹrúsìn rẹ̀, onígbàgbọ́ òdodo.

التفاسير: