Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Tercüme - Ebu Rahime Mikail

Sayfa numarası:close

external-link copy
164 : 7

وَإِذۡ قَالَتۡ أُمَّةٞ مِّنۡهُمۡ لِمَ تَعِظُونَ قَوۡمًا ٱللَّهُ مُهۡلِكُهُمۡ أَوۡ مُعَذِّبُهُمۡ عَذَابٗا شَدِيدٗاۖ قَالُواْ مَعۡذِرَةً إِلَىٰ رَبِّكُمۡ وَلَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ

(Rántí) nígbà tí ìjọ kan nínú wọn wí pé: “Nítorí kí ni ẹ fí ń ṣe wáàsí fún ìjọ kan tí Allāhu máa parẹ́ tàbí tí Ó máa jẹ ní ìyà tó lágbára?” Wọ́n sọ pé: “(Kí ó lè jẹ́) àwáwí lọ́dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu) ni.” info
التفاسير:

external-link copy
165 : 7

فَلَمَّا نَسُواْ مَا ذُكِّرُواْ بِهِۦٓ أَنجَيۡنَا ٱلَّذِينَ يَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلسُّوٓءِ وَأَخَذۡنَا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ بِعَذَابِۭ بَـِٔيسِۭ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ

Nígbà tí wọ́n sì gbàgbé ohun tí wọ́n fi ṣèrántí fún wọn, A gba àwọn tó ń kọ aburú là. A sì fi ìyà tó le jẹ àwọn tó ṣàbòsí nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
166 : 7

فَلَمَّا عَتَوۡاْ عَن مَّا نُهُواْ عَنۡهُ قُلۡنَا لَهُمۡ كُونُواْ قِرَدَةً خَٰسِـِٔينَ

Nígbà tí wọ́n tayọ ẹnu-ààlà níbi ohun tí A kọ̀ fún wọn, A sọ fún wọn pé: “Ẹ di ọ̀bọ, ẹni ìgbéjìnnà sí ìkẹ́.” info
التفاسير:

external-link copy
167 : 7

وَإِذۡ تَأَذَّنَ رَبُّكَ لَيَبۡعَثَنَّ عَلَيۡهِمۡ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَن يَسُومُهُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِۗ إِنَّ رَبَّكَ لَسَرِيعُ ٱلۡعِقَابِ وَإِنَّهُۥ لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ ọ́ di mímọ̀ (fún wọn) pé dájúdájú Òun yóò gbé ẹni tí ó máa fi ìyà burúkú jẹ wọ́n dìde sí wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. info
التفاسير:

external-link copy
168 : 7

وَقَطَّعۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ أُمَمٗاۖ مِّنۡهُمُ ٱلصَّٰلِحُونَ وَمِنۡهُمۡ دُونَ ذَٰلِكَۖ وَبَلَوۡنَٰهُم بِٱلۡحَسَنَٰتِ وَٱلسَّيِّـَٔاتِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ

A dá wọn kékekèle sí orí ilẹ̀ ní ìjọ-ìjọ; àwọn ẹni rere wà nínú wọn, àwọn mìíràn tún wà nínú wọn. A sì fi àwọn ohun rere àti ohun burúkú dán wọn wò kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo). info
التفاسير:

external-link copy
169 : 7

فَخَلَفَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ خَلۡفٞ وَرِثُواْ ٱلۡكِتَٰبَ يَأۡخُذُونَ عَرَضَ هَٰذَا ٱلۡأَدۡنَىٰ وَيَقُولُونَ سَيُغۡفَرُ لَنَا وَإِن يَأۡتِهِمۡ عَرَضٞ مِّثۡلُهُۥ يَأۡخُذُوهُۚ أَلَمۡ يُؤۡخَذۡ عَلَيۡهِم مِّيثَٰقُ ٱلۡكِتَٰبِ أَن لَّا يَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡحَقَّ وَدَرَسُواْ مَا فِيهِۗ وَٱلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ يَتَّقُونَۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ

Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn; wọ́n jogún Tírà (Taorāt àti ’Injīl), wọ́n sì ń gba (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) dúkìá ilé ayé yìí (láti kọ ìkọkúkọ sínú rẹ̀), wọ́n sì ń wí pé: “Wọn yóò foríjìn wá.” Tí (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) dúkìá irú rẹ̀ bá tún wá bá wọn, wọ́n máa gbà á. Ṣé A kò ti bá wọn ṣe àdéhùn nínú Tírà pé, wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo? Wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀! Ilé ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn tó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni? info
التفاسير:

external-link copy
170 : 7

وَٱلَّذِينَ يُمَسِّكُونَ بِٱلۡكِتَٰبِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُصۡلِحِينَ

Àwọn tó sì ń mú Tírà lò dáradára, tí wọ́n ń kírun, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san àwọn tó ń ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ wọn) ráre.[1] info

1. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu - tó ga jùlọ - sọ nípa wọn nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:83-85

التفاسير: