Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Tercüme - Ebu Rahime Mikail

Sayfa numarası:close

external-link copy
131 : 7

فَإِذَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡحَسَنَةُ قَالُواْ لَنَا هَٰذِهِۦۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَطَّيَّرُواْ بِمُوسَىٰ وَمَن مَّعَهُۥٓۗ أَلَآ إِنَّمَا طَٰٓئِرُهُمۡ عِندَ ٱللَّهِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ

Nígbà tí ohun rere bá dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Tiwa ni èyí.” Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á ṣàfitì aburú náà sọ́dọ̀ (Ànábì) Mūsā àti ẹni tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Kíyè sí i, àmì aburú wọn kúkú wà (nínú kádàrá wọn) lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
132 : 7

وَقَالُواْ مَهۡمَا تَأۡتِنَا بِهِۦ مِنۡ ءَايَةٖ لِّتَسۡحَرَنَا بِهَا فَمَا نَحۡنُ لَكَ بِمُؤۡمِنِينَ

Wọ́n sì wí pé: “Ohunkóhun tí o bá mú wá fún wa ní àmì láti fi pidán fún wa, àwa kò níí gbà ọ́ gbọ́.” info
التفاسير:

external-link copy
133 : 7

فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلطُّوفَانَ وَٱلۡجَرَادَ وَٱلۡقُمَّلَ وَٱلضَّفَادِعَ وَٱلدَّمَ ءَايَٰتٖ مُّفَصَّلَٰتٖ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ وَكَانُواْ قَوۡمٗا مُّجۡرِمِينَ

Nítorí náà, A sì fi ẹ̀kún omi, àwọn eṣú, àwọn kòkòrò iná, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ àti ẹ̀jẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn ní àwọn àmì tí ń tẹ̀léra wọn tó fojú hàn. Ńṣe ni wọ́n tún ṣègbéraga; wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
134 : 7

وَلَمَّا وَقَعَ عَلَيۡهِمُ ٱلرِّجۡزُ قَالُواْ يَٰمُوسَى ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَۖ لَئِن كَشَفۡتَ عَنَّا ٱلرِّجۡزَ لَنُؤۡمِنَنَّ لَكَ وَلَنُرۡسِلَنَّ مَعَكَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ

Nígbà tí ìyà sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí, wọ́n wí pé: “Mūsā, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe fún ọ. Dájúdájú tí o bá fi lè gbé ìyà náà kúrò fún wa (pẹ̀lú àdúà rẹ), dájúdájú a máa gbà ọ́ gbọ́, dájúdájú a sì máa jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá ọ lọ.” info
التفاسير:

external-link copy
135 : 7

فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُمُ ٱلرِّجۡزَ إِلَىٰٓ أَجَلٍ هُم بَٰلِغُوهُ إِذَا هُمۡ يَنكُثُونَ

Nígbà tí A gbé ìyà náà kúrò fún wọn fún àkókò kan tí wọn yóò lò (nínú ìṣẹ̀mí wọn), nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn. info
التفاسير:

external-link copy
136 : 7

فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّ بِأَنَّهُمۡ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ عَنۡهَا غَٰفِلِينَ

Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn, A sì tẹ̀ wọ́n rì sínú agbami odò nítorí pé, wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
137 : 7

وَأَوۡرَثۡنَا ٱلۡقَوۡمَ ٱلَّذِينَ كَانُواْ يُسۡتَضۡعَفُونَ مَشَٰرِقَ ٱلۡأَرۡضِ وَمَغَٰرِبَهَا ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَاۖ وَتَمَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ ٱلۡحُسۡنَىٰ عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ بِمَا صَبَرُواْۖ وَدَمَّرۡنَا مَا كَانَ يَصۡنَعُ فِرۡعَوۡنُ وَقَوۡمُهُۥ وَمَا كَانُواْ يَعۡرِشُونَ

A sì jogún àwọn ibùyọ òòrùn lórí ilẹ̀ ayé àti ibùwọ̀ òòrùn rẹ̀, tí A fi ìbùnkún sí, fún àwọn ènìyàn tí wọ́n kà sí ọ̀lẹ. Ọ̀rọ̀ Olúwa Rẹ tó dára sì ṣẹ lórí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nítorí pé, wọ́n ṣe sùúrù. A sì pa ohun tí Fir‘aon àti ìjọ rẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n ń kọ́ nílé run. info
التفاسير: