แปล​ความหมาย​อัลกุรอาน​ - คำแปลภาษาโยรูบา - อบู เราะฮีมะฮ์ มีกาอีล

Al-Mur'salaat

external-link copy
1 : 77

وَٱلۡمُرۡسَلَٰتِ عُرۡفٗا

Allāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 77

فَٱلۡعَٰصِفَٰتِ عَصۡفٗا

Ó fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 77

وَٱلنَّٰشِرَٰتِ نَشۡرٗا

Ó fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 77

فَٱلۡفَٰرِقَٰتِ فَرۡقٗا

Ó fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 77

فَٱلۡمُلۡقِيَٰتِ ذِكۡرًا

Ó fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 77

عُذۡرًا أَوۡ نُذۡرًا

(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 77

إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٞ

Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 77

فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتۡ

Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́, info
التفاسير:

external-link copy
9 : 77

وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتۡ

àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada, info
التفاسير:

external-link copy
10 : 77

وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ نُسِفَتۡ

àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù, info
التفاسير:

external-link copy
11 : 77

وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتۡ

àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn), info
التفاسير:

external-link copy
12 : 77

لِأَيِّ يَوۡمٍ أُجِّلَتۡ

ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná? info
التفاسير:

external-link copy
13 : 77

لِيَوۡمِ ٱلۡفَصۡلِ

Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni. info
التفاسير:

external-link copy
14 : 77

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà? info
التفاسير:

external-link copy
15 : 77

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 77

أَلَمۡ نُهۡلِكِ ٱلۡأَوَّلِينَ

Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí? info
التفاسير:

external-link copy
17 : 77

ثُمَّ نُتۡبِعُهُمُ ٱلۡأٓخِرِينَ

Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun). info
التفاسير:

external-link copy
18 : 77

كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ

Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 77

وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́. info
التفاسير: