แปล​ความหมาย​อัลกุรอาน​ - คำแปลภาษาโยรูบา - อบู เราะฮีมะฮ์ มีกาอีล

หมายเลข​หน้า​:close

external-link copy
19 : 55

مَرَجَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ يَلۡتَقِيَانِ

(Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 55

بَيۡنَهُمَا بَرۡزَخٞ لَّا يَبۡغِيَانِ

Gàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-ààlà (rẹ̀ láààrin ara wọn). info
التفاسير:

external-link copy
21 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
22 : 55

يَخۡرُجُ مِنۡهُمَا ٱللُّؤۡلُؤُ وَٱلۡمَرۡجَانُ

Òkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà. info
التفاسير:

external-link copy
23 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
24 : 55

وَلَهُ ٱلۡجَوَارِ ٱلۡمُنشَـَٔاتُ فِي ٱلۡبَحۡرِ كَٱلۡأَعۡلَٰمِ

Ti (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro tó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga. info
التفاسير:

external-link copy
25 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
26 : 55

كُلُّ مَنۡ عَلَيۡهَا فَانٖ

Gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ máa tán. info
التفاسير:

external-link copy
27 : 55

وَيَبۡقَىٰ وَجۡهُ رَبِّكَ ذُو ٱلۡجَلَٰلِ وَٱلۡإِكۡرَامِ

Ojú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé. info
التفاسير:

external-link copy
28 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
29 : 55

يَسۡـَٔلُهُۥ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ كُلَّ يَوۡمٍ هُوَ فِي شَأۡنٖ

Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́. info
التفاسير:

external-link copy
30 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
31 : 55

سَنَفۡرُغُ لَكُمۡ أَيُّهَ ٱلثَّقَلَانِ

A óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú. info
التفاسير:

external-link copy
32 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
33 : 55

يَٰمَعۡشَرَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِ إِنِ ٱسۡتَطَعۡتُمۡ أَن تَنفُذُواْ مِنۡ أَقۡطَارِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ فَٱنفُذُواْۚ لَا تَنفُذُونَ إِلَّا بِسُلۡطَٰنٖ

Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ kò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára. info
التفاسير:

external-link copy
34 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
35 : 55

يُرۡسَلُ عَلَيۡكُمَا شُوَاظٞ مِّن نَّارٖ وَنُحَاسٞ فَلَا تَنتَصِرَانِ

Wọ́n máa ju ahọ́n iná àti èéfín (tàbí oje idẹ) iná lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì níí lè ranra yín lọ́wọ́. info
التفاسير:

external-link copy
36 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
37 : 55

فَإِذَا ٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتۡ وَرۡدَةٗ كَٱلدِّهَانِ

Nítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa gbígbá. info
التفاسير:

external-link copy
38 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
39 : 55

فَيَوۡمَئِذٖ لَّا يُسۡـَٔلُ عَن ذَنۢبِهِۦٓ إِنسٞ وَلَا جَآنّٞ

Nítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn kò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa). info
التفاسير:

external-link copy
40 : 55

فَبِأَيِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ

Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? info
التفاسير:

external-link copy
41 : 55

يُعۡرَفُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ بِسِيمَٰهُمۡ فَيُؤۡخَذُ بِٱلنَّوَٰصِي وَٱلۡأَقۡدَامِ

Wọ́n máa dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú. info
التفاسير: